Rom 1:29-32

Rom 1:29-32 YBCV

Nwọn kún fun aiṣododo gbogbo, àgbere, ìka, ojukòkoro, arankan; nwọn kún fun ilara, ipania, ija, itanjẹ, iwa-buburu; afi-ọrọ-kẹlẹ banijẹ, Asọrọ ẹni lẹhin, akorira Ọlọrun, alafojudi, agberaga, ahalẹ, alaroṣe ohun buburu, aṣaigbọran si obí, Alainiyè-ninu, ọ̀dalẹ, alainifẹ, agídi, alailãnu: Awọn ẹniti o mọ̀ ilana Ọlọrun pe, ẹniti o ba ṣe irú nkan wọnyi, o yẹ si ikú, nwọn kò ṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn nwọn ni inu didùn si awọn ti nṣe wọn.