Rom 1:18-20

Rom 1:18-20 YBCV

Nitori a fi ibinu Ọlọrun hàn lati ọrun wá si gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun ati aiṣododo enia, awọn ẹniti o fi aiṣododo tẹ otitọ mọ́lẹ̀: Nitori ohun ti ã le mọ̀ niti Ọlọrun o farahàn ninu wọn; nitori Ọlọrun ti fi i hàn fun wọn. Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a da mọ̀ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi