Ifi 4:9-11

Ifi 4:9-11 YBCV

Nigbati awọn ẹda alãye na ba si fi ogo ati ọlá ati ọpẹ́ fun ẹniti o joko lori itẹ́, ti o mbẹ lãye lai ati lailai, Awọn àgba mẹrinlelogun na a si wolẹ niwaju ẹniti o joko lori itẹ́, nwọn a si tẹriba fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai, nwọn a si fi ade wọn lelẹ niwaju itẹ́ na, wipe, Oluwa, iwọ li o yẹ lati gbà ogo ati ọlá ati agbara: nitoripe iwọ li o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni nwọn fi wà ti a si dá wọn.