Ifi 3:15-17

Ifi 3:15-17 YBCV

Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, pe iwọ kò gbóna bẹ̃ni iwọ kò tutù: emi iba fẹ pe ki iwọ kuku tutù, tabi ki iwọ kuku gbóna. Njẹ nitoriti iwọ ṣe ìlọ́wọwọ, ti o kò si gbóna, bẹni o kò tutù, emi o pọ̀ ọ jade kuro li ẹnu mi. Nitoriti iwọ wipe, Emi li ọrọ̀, emi si npọ̀ si i li ọrọ̀, emi kò si ṣe alaini ohunkohun; ti iwọ kò si mọ̀ pe, òṣi ni iwọ, ati àre, ati talakà, ati afọju, ati ẹni-ìhoho