Ifi 3:14-16

Ifi 3:14-16 YBCV

Ati si angẹli ijọ ni Laodikea kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti ijẹ Amin wi, ẹlẹri olododo ati olõtọ, olupilẹṣẹ ẹda Ọlọrun. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, pe iwọ kò gbóna bẹ̃ni iwọ kò tutù: emi iba fẹ pe ki iwọ kuku tutù, tabi ki iwọ kuku gbóna. Njẹ nitoriti iwọ ṣe ìlọ́wọwọ, ti o kò si gbóna, bẹni o kò tutù, emi o pọ̀ ọ jade kuro li ẹnu mi.