Ifi 21:23-26

Ifi 21:23-26 YBCV

Ilu na kò si ni iwá õrùn, tabi oṣupa, lati mã tan imọlẹ si i: nitoripe ogo Ọlọrun li o ntàn imọlẹ si i, Ọdọ-Agutan si ni fitila rẹ̀. Awọn orilẹ-ède yio si mã rìn nipa imọlẹ rẹ̀: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wá sinu rẹ̀. A kì yio si sé awọn ẹnubode rẹ̀ rara li ọsán: nitori kì yio si oru nibẹ̀. Nwọn o si ma mu ogo ati ọlá awọn orilẹ-ède wá sinu rẹ̀.