Ati si angẹli ijọ ni Pergamu kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o ni idà mimu oloju meji nì wipe, Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ibiti iwọ ngbé, ani ibiti ìtẹ Satani wà: ati pe iwọ dì orukọ mi mu ṣinṣin, ti iwọ kò si sẹ́ igbagbọ́ mi, li ọjọ wọnni ninu eyi ti Antipa iṣe olõtọ ajẹrikú mi, ẹniti nwọn pa ninu nyin, nibiti Satani ngbé. Ṣugbọn mo ni nkan diẹ iwi si ọ, nitoriti iwọ ni awọn ti o dì ẹkọ́ ti Balaamu mu nibẹ̀, ẹniti o kọ́ Balaku lati mu ohun ikọsẹ̀ wá siwaju awọn ọmọ Israeli, lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa, ati lati mã ṣe àgbere. Bẹ̃ni iwọ si ní awọn ti o gbà ẹkọ awọn Nikolaitani pẹlu, ohun ti mo korira. Ronupiwada; bikoṣe bẹ̃ emi ó tọ̀ ọ wá nisisiyi, emi o si fi idà ẹnu mi ba wọn jà. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fi manna ti o pamọ́ fun jẹ, emi o si fun u li okuta funfun kan, ati sara okuta na orukọ titun ti a o kọ si i, ti ẹnikẹni kò mọ̀ bikoṣe ẹniti o gbà a.
Kà Ifi 2
Feti si Ifi 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ifi 2:12-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò