Ifi 19:11-14

Ifi 19:11-14 YBCV

Mo si ri ọrun ṣí silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun. Oju rẹ̀ dabi ọwọ iná, ati li ori rẹ̀ ni ade pupọ̀ wà; o si ni orukọ kan ti a kọ, ti ẹnikẹni kò mọ̀, bikoṣe on tikararẹ̀. A si wọ̀ ọ li aṣọ ti a tẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ: a si npè orukọ rẹ̀ ni Ọ̀rọ Ọlọrun. Awọn ogun ti mbẹ li ọrun ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, funfun ati mimọ́, si ntọ ọ lẹhin lori ẹṣin funfun.