Ifi 18:15-16

Ifi 18:15-16 YBCV

Awọn oniṣowo nkan wọnyi, ti a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọrọ̀, yio duro li òkere rére nitori ìbẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã sọkun, nwọn o si mã ṣọ̀fọ, Wipe, Ègbé, egbé ni fun ilu nla nì, ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, ati ti elese aluko, ati ti ododó, ati ti a si fi wura ṣe lọṣọ́, pẹlu okuta iyebiye ati perli!