LẸHIN nkan wọnyi mo si ri angẹli miran, o nti ọrun sọkalẹ wá ti on ti agbara nla; ilẹ aiye si ti ipa ogo rẹ̀ mọlẹ. O si kigbe li ohùn rara, wipe, Babiloni nla ṣubu, o ṣubu, o si di ibujoko awọn ẹmi èṣu, ati ihò ẹmí aimọ́ gbogbo, ati ile ẹiyẹ aimọ́ gbogbo, ati ti ẹiyẹ irira. Nitori nipa ọti-waini irunu àgbere rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ede ṣubu, awọn ọba aiye si ti ba a ṣe àgbere, ati awọn oniṣowo aiye si di ọlọrọ̀ nipa ọ̀pọlọpọ wọbia rẹ̀. Mo si gbọ́ ohùn miran lati ọrun wá, nwipe, Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹnyin enia mi, ki ẹ má bã ṣe alabapin ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ki ẹ má bã si ṣe gbà ninu iyọnu rẹ̀.
Kà Ifi 18
Feti si Ifi 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ifi 18:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò