Angẹli miran si ti inu tẹmpili ti mbẹ li ọrun jade wá, ti on ti doje mimu. Angẹli miran si ti ibi pẹpẹ jade wá, ti o ni agbara lori iná; o si ke li ohùn rara si ẹniti o ni doje mimu, wipe, Tẹ̀ doje rẹ mimu bọ̀ ọ, ki o si rẹ́ awọn idi ajara aiye, nitori awọn eso rẹ̀ ti pọ́n. Angẹli na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ilẹ aiye, o si ké ajara ilẹ aiye, o si kó o lọ sinu ifúnti, ifúnti nla ibinu Ọlọrun. A si tẹ̀ ifúnti na lẹhin odi ilu na, ẹ̀jẹ si ti inu ifúnti na jade, ani ti o tó okùn ijanu ẹṣin jinna to ẹgbẹjọ furlongi.
Kà Ifi 14
Feti si Ifi 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ifi 14:17-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò