Ifi 14:12-13

Ifi 14:12-13 YBCV

Nihin ni sũru awọn enia mimọ́ gbé wà: awọn ti npa ofin Ọlọrun ati igbagbọ́ Jesu mọ́. Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá nwi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Alabukún fun li awọn okú ti o kú nipa ti Oluwa lati ìhin lọ: Bẹni, li Ẹmí wi, ki nwọn ki o le simi kuro ninu lãlã wọn, nitori iṣẹ wọn ntọ̀ wọn lẹhin.