Ifi 12:7-11

Ifi 12:7-11 YBCV

Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na jàgun; dragoni si jàgun ati awọn angẹli rẹ̀. Nwọn kò si le ṣẹgun; bẹ̃ni a kò si ri ipo wọn mọ́ li ọrun. A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀. Mo si gbọ́ ohùn rara li ọrun, nwipe, Nigbayi ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisùn awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsán ati loru. Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọ̀rọ ẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn ani titi de ikú.