O. Daf 98:1-2

O. Daf 98:1-2 YBCV

Ẹ kọrin titun si Oluwa; nitoriti o ti ṣe ohun iyanu: ọwọ ọtún rẹ̀, ati apa rẹ̀ mimọ́ li o ti mu igbala wa fun ara rẹ̀. Oluwa ti sọ igbala rẹ̀ di mimọ̀: ododo rẹ̀ li o ti fi hàn nigbangba li ojú awọn keferi.