Ẹ kọrin titun si Oluwa: ẹ kọrin si Oluwa gbogbo aiye. Ẹ kọrin si Oluwa, fi ibukún fun orukọ rẹ̀; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ. Sọ̀rọ ogo rẹ̀ lãrin awọn keferi, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ lãrin gbogbo enia. Nitori ti Oluwa tobi, o si ni iyìn pupọ̀pupọ̀: on li o ni ìbẹru jù gbogbo oriṣa lọ. Nitori pe gbogbo oriṣa orilẹ-ède asan ni nwọn: ṣugbọn Oluwa li o da ọrun. Ọlá ati ọla-nla li o wà niwaju rẹ̀: ipa ati ẹwà mbẹ ninu ibi mimọ́ rẹ̀. Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipá fun Oluwa. Ẹ fi ogo fun orukọ Oluwa: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá si agbala rẹ̀. Ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́: ẹ wariri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye. Ẹ wi lãrin awọn keferi pe, Oluwa jọba: nitõtọ a o fi idi aiye mulẹ ti kì yio le yẹ̀: on o fi ododo ṣe idajọ enia. Jẹ ki ọrun ki o yọ̀, jẹ ki inu aiye ki o dùn; jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀. Jẹ ki oko ki o kún fun ayọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: nigbana ni gbogbo igi igbo yio ma yọ̀. Niwaju Oluwa: nitoriti mbọwa, nitori ti mbọwa ṣe idajọ aiye: yio fi ododo ṣe idajọ aiye, ati ti enia ni yio fi otitọ rẹ̀ ṣe.
Kà O. Daf 96
Feti si O. Daf 96
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 96:1-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò