O. Daf 92:1-5

O. Daf 92:1-5 YBCV

OHUN rere ni lati ma fi ọpẹ fun Oluwa, ati lati ma kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo: Lati ma fi iṣeun ifẹ rẹ hàn li owurọ, ati otitọ rẹ li alalẹ. Lara ohun-elo orin olokùn mẹwa, ati lara ohun-elo orin mimọ́: lara duru pẹlu iró ti o ni ironu. Nitori iwọ, Oluwa, li o ti mu mi yọ̀ nipa iṣẹ rẹ: emi o ma kọrin iyìn nitori iṣẹ ọwọ rẹ. Oluwa, iṣẹ rẹ ti tobi to! ìro-inu rẹ jinlẹ gidigidi.