Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, tani Oluwa alagbara bi iwọ? tabi bi otitọ rẹ ti o yi ọ ká. Iwọ li o jọba ibinu okun; nigbati riru omi rẹ̀ dide, iwọ mu u pa rọrọ. Iwọ li o ti ya Rahabu pẹrẹ-pẹrẹ bi ẹniti a pa; iwọ ti fi apa ọwọ́ agbara rẹ tú awọn ọtá rẹ ká. Ọrun ni tirẹ, aiye pẹlu ni tirẹ: aiye ati ẹ̀kun rẹ̀, iwọ li o ti ṣe ipilẹ wọn. Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ. Iwọ ni apá agbara: agbara li ọwọ́ rẹ, giga li ọwọ ọtún rẹ. Otitọ ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ: ãnu ati otitọ ni yio ma lọ siwaju rẹ. Ibukún ni fun awọn enia ti o mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa, nwọn o ma rìn ni imọlẹ oju rẹ. Li orukọ rẹ ni nwọn o ma yọ̀ li ọjọ gbogbo: ati ninu ododo rẹ li a o ma gbé wọn leke. Nitori iwọ li ogo agbara wọn: ati ninu ore ojurere rẹ li a o gbé iwo wa soke, Nitori Oluwa li asà wa: Ẹni-Mimọ́ Israeli li ọba wa.
Kà O. Daf 89
Feti si O. Daf 89
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 89:8-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò