O. Daf 89:19-52

O. Daf 89:19-52 YBCV

Nigbana ni iwọ sọ li oju iran fun ayanfẹ rẹ, o si wipe, Emi ti gbé iranlọwọ ru ẹni-alagbara; emi ti gbé ẹnikan leke ti a yàn ninu awọn enia. Emi ti ri Dafidi, iranṣẹ mi; ororo mi mimọ́ ni mo ta si i li ori: Nipasẹ ẹniti a o fi ọwọ mi mulẹ: apá mi pẹlu yio ma mu u li ara le. Ọtá kì yio bère lọdọ rẹ̀; bẹ̃ni awọn ọmọ iwà-buburu kì yio pọ́n ọ loju. Emi o si lu awọn ọta rẹ̀ bolẹ niwaju rẹ̀, emi o si yọ awọn ti o korira rẹ̀ lẹnu. Ṣugbọn otitọ mi ati ãnu mi yio wà pẹlu rẹ̀; ati li orukọ mi li a o gbé iwo rẹ̀ soke. Emi o gbé ọwọ rẹ̀ le okun, ati ọwọ ọtún rẹ̀ le odò nla nì. On o kigbe pè mi pe, Iwọ ni baba mi, Ọlọrun mi, ati apata igbala mi. Emi o si ṣe e li akọbi, Ẹni-giga jù awọn ọba aiye lọ. Ãnu mi li emi o pamọ́ fun u lailai, ati majẹmu mi yio si ba a duro ṣinṣin. Irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu li emi o mu pẹ titi, ati itẹ́ rẹ̀ bi ọjọ ọrun. Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba kọ̀ ofin mi silẹ, ti nwọn kò si rìn nipa idajọ mi; Bi nwọn ba bá ilana mi jẹ, ti nwọn kò si pa ofin mi mọ́, Nigbana li emi o fi ọgọ bẹ irekọja wọn wò, ati ẹ̀ṣẹ wọn pẹlu ìna. Ṣugbọn iṣeun-ifẹ mi li emi kì yio gbà lọwọ rẹ̀, bẹ̃li emi kì yio jẹ ki otitọ mi ki o yẹ̀. Majẹmu mi li emi kì yio dà, bẹ̃li emi kì yio yi ohun ti o ti ète mi jade pada. Lẹrinkan ni mo ti fi ìwa-mimọ́ mi bura pe, emi kì yio purọ fun Dafidi. Iru-ọmọ rẹ̀ yio duro titi lailai, ati itẹ́ rẹ̀ bi õrun niwaju mi. A o fi idi rẹ̀ mulẹ lailai bi òṣupa, ati bi ẹlẹri otitọ li ọrun. Ṣugbọn iwọ ti ṣa tì, iwọ si korira, iwọ ti binu si Ẹni-ororo rẹ. Iwọ ti sọ majẹmu iranṣẹ rẹ di ofo: iwọ ti sọ ade rẹ̀ si ilẹ. Iwọ ti fa ọgba rẹ̀ gbogbo ya: iwọ ti mu ilu-olodi rẹ̀ di ahoro. Gbogbo awọn ti nkọja lọ li ọ̀na nfi ṣe ijẹ: on si di ẹ̀gan fun awọn aladugbo rẹ̀. Iwọ ti gbé ọwọ ọtún awọn ọta rẹ̀ soke; iwọ mu gbogbo awọn ọta rẹ̀ yọ̀. Iwọ si ti yi oju idà rẹ̀ pada pẹlu, iwọ kò si mu u duro li oju ogun. Iwọ ti mu ogo rẹ̀ tẹ́, iwọ si wọ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ-yilẹ. Ọjọ ewe rẹ̀ ni iwọ ke kuru; iwọ fi itìju bò o. Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o pa ara rẹ mọ́ lailai? ibinu rẹ yio ha jo bi iná bi? Ranti bi ọjọ mi ti kuru to; ẽse ti iwọ ha da gbogbo enia lasan? Ọkunrin wo li o wà lãye, ti kì yio ri ikú? ti yio gbà ọkàn rẹ̀ lọwọ isa-okú. Oluwa, nibo ni iṣeun-ifẹ rẹ atijọ wà, ti iwọ bura fun Dafidi ninu otitọ rẹ? Oluwa, ranti ẹ̀gan awọn iranṣẹ rẹ, ti emi nrù li aiya mi lati ọdọ gbogbo ọ̀pọ enia. Ti awọn ọta rẹ fi kẹgàn, Oluwa: ti nwọn fi ngàn ipasẹ Ẹni-ororo rẹ. Olubukún ni Oluwa si i titi lailai. Amin ati Amin.