Nigbana ni iwọ sọ li oju iran fun ayanfẹ rẹ, o si wipe, Emi ti gbé iranlọwọ ru ẹni-alagbara; emi ti gbé ẹnikan leke ti a yàn ninu awọn enia. Emi ti ri Dafidi, iranṣẹ mi; ororo mi mimọ́ ni mo ta si i li ori: Nipasẹ ẹniti a o fi ọwọ mi mulẹ: apá mi pẹlu yio ma mu u li ara le. Ọtá kì yio bère lọdọ rẹ̀; bẹ̃ni awọn ọmọ iwà-buburu kì yio pọ́n ọ loju. Emi o si lu awọn ọta rẹ̀ bolẹ niwaju rẹ̀, emi o si yọ awọn ti o korira rẹ̀ lẹnu. Ṣugbọn otitọ mi ati ãnu mi yio wà pẹlu rẹ̀; ati li orukọ mi li a o gbé iwo rẹ̀ soke. Emi o gbé ọwọ rẹ̀ le okun, ati ọwọ ọtún rẹ̀ le odò nla nì. On o kigbe pè mi pe, Iwọ ni baba mi, Ọlọrun mi, ati apata igbala mi. Emi o si ṣe e li akọbi, Ẹni-giga jù awọn ọba aiye lọ. Ãnu mi li emi o pamọ́ fun u lailai, ati majẹmu mi yio si ba a duro ṣinṣin. Irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu li emi o mu pẹ titi, ati itẹ́ rẹ̀ bi ọjọ ọrun. Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba kọ̀ ofin mi silẹ, ti nwọn kò si rìn nipa idajọ mi; Bi nwọn ba bá ilana mi jẹ, ti nwọn kò si pa ofin mi mọ́, Nigbana li emi o fi ọgọ bẹ irekọja wọn wò, ati ẹ̀ṣẹ wọn pẹlu ìna. Ṣugbọn iṣeun-ifẹ mi li emi kì yio gbà lọwọ rẹ̀, bẹ̃li emi kì yio jẹ ki otitọ mi ki o yẹ̀. Majẹmu mi li emi kì yio dà, bẹ̃li emi kì yio yi ohun ti o ti ète mi jade pada. Lẹrinkan ni mo ti fi ìwa-mimọ́ mi bura pe, emi kì yio purọ fun Dafidi. Iru-ọmọ rẹ̀ yio duro titi lailai, ati itẹ́ rẹ̀ bi õrun niwaju mi. A o fi idi rẹ̀ mulẹ lailai bi òṣupa, ati bi ẹlẹri otitọ li ọrun.
Kà O. Daf 89
Feti si O. Daf 89
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 89:19-37
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò