O. Daf 89:1-4

O. Daf 89:1-4 YBCV

EMI o ma kọrin ãnu Oluwa lailai: ẹnu mi li emi o ma fi fi otitọ rẹ hàn lati irandiran. Nitori ti emi ti wipe, A o gbé ãnu ró soke lailai: otitọ rẹ ni iwọ o gbé kalẹ li ọrun. Emi ti bá ayànfẹ mi da majẹmu, emi ti bura fun Dafidi, iranṣẹ mi, Irú-ọmọ rẹ li emi o gbé kalẹ lailai, emi o si ma gbé itẹ́ rẹ ró lati irandiran