O. Daf 89:1-29

O. Daf 89:1-29 YBCV

EMI o ma kọrin ãnu Oluwa lailai: ẹnu mi li emi o ma fi fi otitọ rẹ hàn lati irandiran. Nitori ti emi ti wipe, A o gbé ãnu ró soke lailai: otitọ rẹ ni iwọ o gbé kalẹ li ọrun. Emi ti bá ayànfẹ mi da majẹmu, emi ti bura fun Dafidi, iranṣẹ mi, Irú-ọmọ rẹ li emi o gbé kalẹ lailai, emi o si ma gbé itẹ́ rẹ ró lati irandiran, Ọrun yio si ma yìn iṣẹ-iyanu rẹ, Oluwa, otitọ rẹ pẹlu ninu ijọ enia mimọ́ rẹ. Nitori pe, tali o wà li ọrun ti a le fi wé Oluwa? tani ninu awọn ọmọ alagbara, ti a le fi wé Oluwa? Ọlọrun li o ni ìbẹru gidigidi ni ijọ enia mimọ́, o si ni ibuyìn-fun lati ọdọ gbogbo awọn ti o yi i ká. Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, tani Oluwa alagbara bi iwọ? tabi bi otitọ rẹ ti o yi ọ ká. Iwọ li o jọba ibinu okun; nigbati riru omi rẹ̀ dide, iwọ mu u pa rọrọ. Iwọ li o ti ya Rahabu pẹrẹ-pẹrẹ bi ẹniti a pa; iwọ ti fi apa ọwọ́ agbara rẹ tú awọn ọtá rẹ ká. Ọrun ni tirẹ, aiye pẹlu ni tirẹ: aiye ati ẹ̀kun rẹ̀, iwọ li o ti ṣe ipilẹ wọn. Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ. Iwọ ni apá agbara: agbara li ọwọ́ rẹ, giga li ọwọ ọtún rẹ. Otitọ ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ: ãnu ati otitọ ni yio ma lọ siwaju rẹ. Ibukún ni fun awọn enia ti o mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa, nwọn o ma rìn ni imọlẹ oju rẹ. Li orukọ rẹ ni nwọn o ma yọ̀ li ọjọ gbogbo: ati ninu ododo rẹ li a o ma gbé wọn leke. Nitori iwọ li ogo agbara wọn: ati ninu ore ojurere rẹ li a o gbé iwo wa soke, Nitori Oluwa li asà wa: Ẹni-Mimọ́ Israeli li ọba wa. Nigbana ni iwọ sọ li oju iran fun ayanfẹ rẹ, o si wipe, Emi ti gbé iranlọwọ ru ẹni-alagbara; emi ti gbé ẹnikan leke ti a yàn ninu awọn enia. Emi ti ri Dafidi, iranṣẹ mi; ororo mi mimọ́ ni mo ta si i li ori: Nipasẹ ẹniti a o fi ọwọ mi mulẹ: apá mi pẹlu yio ma mu u li ara le. Ọtá kì yio bère lọdọ rẹ̀; bẹ̃ni awọn ọmọ iwà-buburu kì yio pọ́n ọ loju. Emi o si lu awọn ọta rẹ̀ bolẹ niwaju rẹ̀, emi o si yọ awọn ti o korira rẹ̀ lẹnu. Ṣugbọn otitọ mi ati ãnu mi yio wà pẹlu rẹ̀; ati li orukọ mi li a o gbé iwo rẹ̀ soke. Emi o gbé ọwọ rẹ̀ le okun, ati ọwọ ọtún rẹ̀ le odò nla nì. On o kigbe pè mi pe, Iwọ ni baba mi, Ọlọrun mi, ati apata igbala mi. Emi o si ṣe e li akọbi, Ẹni-giga jù awọn ọba aiye lọ. Ãnu mi li emi o pamọ́ fun u lailai, ati majẹmu mi yio si ba a duro ṣinṣin. Irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu li emi o mu pẹ titi, ati itẹ́ rẹ̀ bi ọjọ ọrun.