O. Daf 89:1-18

O. Daf 89:1-18 YBCV

EMI o ma kọrin ãnu Oluwa lailai: ẹnu mi li emi o ma fi fi otitọ rẹ hàn lati irandiran. Nitori ti emi ti wipe, A o gbé ãnu ró soke lailai: otitọ rẹ ni iwọ o gbé kalẹ li ọrun. Emi ti bá ayànfẹ mi da majẹmu, emi ti bura fun Dafidi, iranṣẹ mi, Irú-ọmọ rẹ li emi o gbé kalẹ lailai, emi o si ma gbé itẹ́ rẹ ró lati irandiran, Ọrun yio si ma yìn iṣẹ-iyanu rẹ, Oluwa, otitọ rẹ pẹlu ninu ijọ enia mimọ́ rẹ. Nitori pe, tali o wà li ọrun ti a le fi wé Oluwa? tani ninu awọn ọmọ alagbara, ti a le fi wé Oluwa? Ọlọrun li o ni ìbẹru gidigidi ni ijọ enia mimọ́, o si ni ibuyìn-fun lati ọdọ gbogbo awọn ti o yi i ká. Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, tani Oluwa alagbara bi iwọ? tabi bi otitọ rẹ ti o yi ọ ká. Iwọ li o jọba ibinu okun; nigbati riru omi rẹ̀ dide, iwọ mu u pa rọrọ. Iwọ li o ti ya Rahabu pẹrẹ-pẹrẹ bi ẹniti a pa; iwọ ti fi apa ọwọ́ agbara rẹ tú awọn ọtá rẹ ká. Ọrun ni tirẹ, aiye pẹlu ni tirẹ: aiye ati ẹ̀kun rẹ̀, iwọ li o ti ṣe ipilẹ wọn. Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ. Iwọ ni apá agbara: agbara li ọwọ́ rẹ, giga li ọwọ ọtún rẹ. Otitọ ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ: ãnu ati otitọ ni yio ma lọ siwaju rẹ. Ibukún ni fun awọn enia ti o mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa, nwọn o ma rìn ni imọlẹ oju rẹ. Li orukọ rẹ ni nwọn o ma yọ̀ li ọjọ gbogbo: ati ninu ododo rẹ li a o ma gbé wọn leke. Nitori iwọ li ogo agbara wọn: ati ninu ore ojurere rẹ li a o gbé iwo wa soke, Nitori Oluwa li asà wa: Ẹni-Mimọ́ Israeli li ọba wa.