O. Daf 86:11-13

O. Daf 86:11-13 YBCV

Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o ma rìn ninu otitọ rẹ: mu aiya mi ṣọkan lati bẹ̀ru orukọ rẹ. Emi o yìn ọ, Oluwa Ọlọrun mi, tinutinu mi gbogbo: emi o si ma fi ogo fun orukọ rẹ titi lai. Nitoripe nla li ãnu rẹ si mi: iwọ si ti gbà ọkàn mi lọwọ isa-okú jijin.