O. Daf 81:8-14

O. Daf 81:8-14 YBCV

Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si jẹri si ọ: Israeli, bi iwọ ba fetisi mi. Kì yio si ọlọrun miran ninu nyin; bẹ̃ni iwọ kì yio sìn ọlọrun àjeji. Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti jade wá: yà ẹ̀nu rẹ̀ gbòro, emi o si kún u. Ṣugbọn awọn enia mi kò fẹ igbọ́ ohùn mi; Israeli kò si fẹ ti emi. Bẹ̃ni mo fi wọn silẹ fun lile aiya wọn: nwọn si nrìn ninu ero ara wọn. Ibaṣepe awọn enia mi ti gbọ́ ti emi, ati ki Israeli ki o ma rìn nipa ọ̀na mi! Emi iba ti ṣẹ́ awọn ọta wọn lọgan, emi iba si ti yi ọwọ mi pada si awọn ọta wọn.