O. Daf 8:5-8

O. Daf 8:5-8 YBCV

Iwọ sa da a li onirẹlẹ diẹ jù Ọlọrun lọ, iwọ si ti fi ogo ati ọlá de e li ade. Iwọ mu u jọba iṣẹ ọwọ rẹ; iwọ si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀; Awọn agutan ati awọn malu pẹlu, ati awọn ẹranko igbẹ; Awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹja okun, ti o nkọja lọ nipa ọ̀na okun.