O. Daf 8:1-2

O. Daf 8:1-2 YBCV

OLUWA, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye! iwọ ti o gbé ogo rẹ kà ori awọn ọrun. Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ ati ọmọ-ọmu ni iwọ ti ṣe ilana agbara, nitori awọn ọta rẹ, nitori ki iwọ ki o le mu ọta olugbẹsan nì dakẹjẹ.