O. Daf 78:32-72

O. Daf 78:32-72 YBCV

Ninu gbogbo wọnyi nwọn nṣẹ̀ siwaju, nwọn kò si gbà iṣẹ iyanu rẹ̀ gbọ́. Nitorina li o ṣe run ọjọ wọn li asan, ati ọdun wọn ni ijaiya. Nigbati o pa wọn, nigbana ni nwọn wá a kiri: nwọn si pada, nwọn bère Ọlọrun lakokò, Nwọn si ranti pe, Ọlọrun li apata wọn, ati Ọlọrun Ọga-ogo li Oludande wọn, Ṣugbọn ẹnu wọn ni nwọn fi pọ́n ọ, nwọn si fi ahọn wọn ṣeke si i. Nitori ọkàn wọn kò ṣe dẽde pẹlu rẹ̀, bẹ̃ni nwọn kò si duro ṣinṣin ni majẹmu rẹ̀. Ṣugbọn on, o kún fun iyọ́nu, o fi ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn, kò si run wọn: nitõtọ, nigba pupọ̀ li o yi ibinu rẹ̀ pada, ti kò si ru gbogbo ibinu rẹ̀ soke. Nitoriti o ranti pe, enia ṣa ni nwọn; afẹfẹ ti nkọja lọ, ti kò si tun pada wá mọ. Igba melo-melo ni nwọn sọ̀tẹ si i li aginju, ti nwọn si bà a ninu jẹ ninu aṣálẹ! Nitõtọ, nwọn yipada, nwọn si dan Ọlọrun wò, nwọn si ṣe aropin Ẹni-Mimọ́ Israeli. Nwọn kò ranti ọwọ rẹ̀, tabi ọjọ nì ti o gbà wọn lọwọ ọta. Bi o ti ṣe iṣẹ-àmi rẹ̀ ni Egipti, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ni igbẹ Soani. Ti o si sọ odò wọn di ẹ̀jẹ; ati omi ṣiṣan wọn, ti nwọn kò fi le mu u. O rán eṣinṣin sinu wọn, ti o jẹ wọn; ati ọpọlọ, ti o run wọn. O fi eso ilẹ wọn fun kokoro pẹlu, ati iṣẹ wọn fun ẽṣú. O fi yinyin pa àjara wọn, o si fi yinyin nla pa igi sikamore wọn. O fi ohun ọ̀sin wọn pẹlu fun yinyin, ati agbo-ẹran wọn fun manamana. O mu kikoro ibinu rẹ̀ wá si wọn lara, irunu ati ikannu, ati ipọnju, nipa riran angeli ibi sinu wọn. O ṣina silẹ fun ibinu rẹ̀; kò da ọkàn wọn si lọwọ ikú, ṣugbọn o fi ẹmi wọn fun àjakalẹ-àrun. O si kọlu gbogbo awọn akọbi ni Egipti, olori agbara wọn ninu agọ Hamu: Ṣugbọn o mu awọn enia tirẹ̀ lọ bi agutan, o si ṣe itọju wọn ni iju bi agbo-ẹran. O si ṣe amọna wọn li alafia, bẹ̃ni nwọn kò si bẹ̀ru: ṣugbọn okun bò awọn ọta wọn mọlẹ. O si mu wọn wá si eti ibi-mimọ́ rẹ̀, ani si òke yi ti ọwọ ọtún rẹ̀ ti rà. O tì awọn keferi jade pẹlu kuro niwaju wọn, o si fi tita okùn pinlẹ fun wọn ni ilẹ-ini, o si mu awọn ẹya Israeli joko ninu agọ wọn. Ṣugbọn nwọn dan a wò, nwọn si ṣọ̀tẹ si Ọlọrun Ọga-ogo, nwọn kò si pa ẹri rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn nwọn yipada, nwọn ṣe alaiṣotitọ bi awọn baba wọn: nwọn si pẹhinda si apakan bi ọrun ẹ̀tan. Nitori ti nwọn fi ibi giga wọn bi i ninu, nwọn si fi ere finfin wọn mu u jowu. Nigbati Ọlọrun gbọ́ eyi, o binu, o si korira Israeli gidigidi. Bẹ̃li o kọ̀ agọ Ṣilo silẹ, agọ ti o pa ninu awọn enia. O si fi agbara rẹ̀ fun igbekun, ati ogo rẹ̀ le ọwọ ọta nì. O fi awọn enia rẹ̀ fun idà pẹlu; o si binu si ilẹ-ini rẹ̀. Iná run awọn ọdọmọkunrin wọn; a kò si fi orin sin awọn wundia wọn ni iyawo. Awọn alufa wọn ti oju idà ṣubu; awọn opó wọn kò si pohunrere ẹkún. Nigbana li Oluwa ji bi ẹnipe loju orun, ati bi alagbara ti o nkọ nitori ọti-waini. O si kọlu awọn ọta rẹ̀ lẹhin; o sọ wọn di ẹ̀gan titi aiye. Pẹlupẹlu o kọ̀ agọ Josefu, kò si yàn ẹ̀ya Efraimu: Ṣugbọn o yan ẹ̀ya Juda, òke Sioni ti o fẹ. O si kọ́ ibi-mimọ́ rẹ̀ bi òke-ọrun bi ilẹ ti o ti fi idi rẹ̀ mulẹ lailai. O si yàn Dafidi iranṣẹ rẹ̀, o si mu u kuro lati inu agbo-agutan wá: Lati má tọ̀ awọn agutan lẹhin, ti o tobi fun oyun, o mu u lati ma bọ́ Jakobu, enia rẹ̀, ati Israeli, ilẹ-ini rẹ̀. Bẹ̃li o bọ́ wọn gẹgẹ bi ìwa-titọ inu rẹ̀; o si fi ọgbọ́n ọwọ rẹ̀ ṣe amọna wọn.