O. Daf 78:21-25

O. Daf 78:21-25 YBCV

Nitorina, Oluwa gbọ́ eyi, o binu: bẹ̃ni iná ràn ni Jakobu, ibinu si ru ni Israeli; Nitori ti nwọn kò gbà Ọlọrun gbọ́, nwọn kò si gbẹkẹle igbala rẹ̀. O paṣẹ fun awọsanma lati òke wá, o si ṣi ilẹkùn ọrun silẹ. O si rọ̀jo Manna silẹ fun wọn ni jijẹ, o si fun wọn li ọkà ọrun. Enia jẹ onjẹ awọn angeli; o rán onjẹ si wọn li ajẹyo.