O. Daf 77:6-15

O. Daf 77:6-15 YBCV

Mo ranti orin mi li oru: emi mba aiya mi sọ̀rọ: ọkàn mi si nṣe awari jọjọ. Oluwa yio ha ṣa ni tì lailai? kì o si ṣe oju rere mọ́? Anu rẹ̀ ha lọ lailai? ileri rẹ̀ ha yẹ̀ titi lai? Ọlọrun ha gbagbe lati ṣe oju rere? ninu ibinu rẹ̀ o ha sé irọnu ãnu rẹ̀ mọ́? Emi wipe, Eyi li ailera mi! eyi li ọdun ọwọ ọtún Ọga-ogo! Emi o ranti iṣẹ Oluwa: nitõtọ emi o ranti iṣẹ iyanu rẹ atijọ. Ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro gbogbo iṣẹ rẹ pẹlu, emi o si ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ. Ọlọrun, ọ̀na rẹ mbẹ ninu ìwa-mimọ́: tali alagbara ti o tobi bi Ọlọrun? Iwọ li Alagbara ti nṣe iṣẹ iyanu: iwọ li o ti fi ipá rẹ hàn ninu awọn enia. Iwọ li o ti fi apá rẹ rà awọn enia rẹ pada, awọn ọmọ Jakobu ati Josefu.