O. Daf 77:16-20

O. Daf 77:16-20 YBCV

Omi ri ọ, Ọlọrun, omi ri ọ, ẹ̀ru bà wọn: nitõtọ ara ibú kò balẹ. Awọsanma dà omi silẹ: ojusanma rán iró jade: ọfà rẹ jade lọ pẹlu. Ohùn ãrá rẹ nsan li ọrun: manamana nkọ si aiye, ilẹ nwa-rìri, o si mì. Ọ̀na rẹ mbẹ li okun, ati ipa rẹ ninu awọn omi nla, ipasẹ rẹ li a kò si mọ̀. Iwọ dà awọn enia rẹ bi ọ̀wọ-ẹran nipa ọwọ Mose ati Aaroni.