O. Daf 74:18-22

O. Daf 74:18-22 YBCV

Ranti eyi, Oluwa, pe ọta nkẹgàn, ati pe awọn enia buburu nsọ̀rọ odi si orukọ rẹ. Máṣe fi ọkàn àdaba rẹ le ẹranko igbẹ lọwọ: máṣe gbagbe ijọ awọn talaka rẹ lailai. Juba majẹmu nì: nitori ibi òkunkun aiye wọnni o kún fun ibugbe ìka. Máṣe jẹ ki ẹniti a ni lara ki o pada ni ìtiju; jẹ ki talaka ati alaini ki o yìn orukọ rẹ. Ọlọrun, dide, gbà ẹjọ ara rẹ rò: ranti bi aṣiwere enia ti ngàn ọ lojojumọ.