O. Daf 74:12-17

O. Daf 74:12-17 YBCV

Nitori Ọlọrun li Ọba mi li atijọ wá, ti nṣiṣẹ igbala lãrin aiye. Iwọ li o ti yà okun ni meji nipa agbara rẹ: iwọ ti fọ́ ori awọn erinmi ninu omi. Iwọ fọ́ ori Lefiatani tũtu, o si fi i ṣe onjẹ fun awọn ti ngbe inu ijù. Iwọ là orisun ati iṣan-omi: iwọ gbẹ awọn odò nla. Tirẹ li ọsán, tirẹ li oru pẹlu: iwọ li o ti pèse imọlẹ ati õrun. Iwọ li o ti pàla eti aiye: iwọ li o ṣe igba ẹ̀run ati igba otutu.