O. Daf 74:1-3

O. Daf 74:1-3 YBCV

ỌLỌRUN, ẽṣe ti iwọ fi ta wa nù titi lai! ẽṣe ti ibinu rẹ fi nrú si agutan papa rẹ? Ranti ijọ enia rẹ ti iwọ ti rà nigba atijọ; ilẹ-ini rẹ ti iwọ ti rà pada; òke Sioni yi, ninu eyi ti iwọ ngbe. Gbé ẹsẹ rẹ soke si ahoro lailai nì; ani si gbogbo eyiti ọta ti fi buburu ṣe ni ibi-mimọ́.