O. Daf 73:1-5

O. Daf 73:1-5 YBCV

NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan. Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu. Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀. Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran.