O. Daf 72:7-17

O. Daf 72:7-17 YBCV

Li ọjọ rẹ̀ li awọn olododo yio gbilẹ: ati ọ̀pọlopọ alafia niwọn bi òṣupa yio ti pẹ to. On o si jọba lati okun de okun, ati lati odò nì de opin aiye. Awọn ti o joko li aginju yio tẹriba fun u; awọn ọta rẹ̀ yio si lá erupẹ ilẹ. Awọn ọba Tarṣiṣi, ati ti awọn erekuṣu yio mu ọrẹ wá: awọn ọba Ṣeba ati ti Seba yio mu ẹ̀bun wá. Nitõtọ, gbogbo awọn ọba ni yio wolẹ niwaju rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma sìn i. Nitori yio gbà alaini nigbati o ba nke: talaka pẹlu, ati ẹniti kò li oluranlọwọ. On o da talaka ati alaini si, yio si gbà ọkàn awọn alaini là. On o rà ọkàn wọn pada lọwọ ẹ̀tan ati ìwa-agbara: iyebiye si li ẹ̀jẹ wọn li oju rẹ̀. On o si yè, on li a o si fi wura Ṣeba fun: a o si ma gbadura fun u nigbagbogbo: lojojumọ li a o si ma yìn i. Ikúnwọ ọkà ni yio ma wà lori ilẹ, lori awọn òke nla li eso rẹ̀ yio ma mì bi Lebanoni: ati awọn ti inu ilu yio si ma gbà bi koriko ilẹ. Orukọ rẹ̀ yio wà titi lai: orukọ rẹ̀ yio ma gbilẹ niwọn bi õrun yio ti pẹ to: nwọn o si ma bukún fun ara wọn nipaṣẹ rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma pè e li alabukúnfun.