O. Daf 71:3-6

O. Daf 71:3-6 YBCV

Iwọ ni ki o ṣe ibujoko apata mi, nibiti emi o gbe ma rè nigbagbogbo: iwọ ti paṣẹ lati gbà mi; nitori iwọ li apata ati odi agbara mi. Gbà mi, Ọlọrun mi, li ọwọ awọn enia buburu, li ọwọ alaiṣododo ati ìka ọkunrin. Nitori iwọ ni ireti mi, Oluwa Ọlọrun; iwọ ni igbẹkẹle mi lati igba ewe mi. Ọwọ rẹ li a ti fi gbé mi duro lati inu wá: iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu iya mi wá: nipasẹ rẹ ni iyìn mi wà nigbagbogbo.