Ṣugbọn emi o ma reti nigbagbogbo, emi o si ma fi iyìn kún iyìn rẹ. Ẹnu mi yio ma fi ododo rẹ ati igbala rẹ hàn li ọjọ gbogbo; emi kò sa mọ̀ iye rẹ̀. Emi o wá li agbara Oluwa Ọlọrun; emi o ma da ọ̀rọ ododo rẹ sọ, ani tirẹ nikan. Ọlọrun, iwọ ti kọ́ mi lati igba ewe mi wá: ati di isisiyi li emi ti nsọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ. Pẹlupẹlu, nigbati emi di arugbo tan ti mo hewu, Ọlọrun máṣe kọ̀ mi; titi emi o fi fi ipá rẹ hàn fun iran yi, ati agbara rẹ fun gbogbo awọn ara ẹ̀hin. Ọlọrun ododo rẹ ga jọjọ pẹlu, ẹniti o ti nṣe nkan nla: Ọlọrun, tali o dabi iwọ! Iwọ ti o fi iṣẹ nla ati kikan hàn mi, ni yio si tun mi ji, yio si tun mu mi sọ si òke lati ọgbun ilẹ wá. Iwọ o sọ ọlá mi di pupọ̀, iwọ o si tù mi ninu niha gbogbo. Emi o si fi ohun-elo orin yìn ọ pẹlu, ani otitọ rẹ, Ọlọrun mi: iwọ li emi o ma fi duru kọrin si, iwọ Ẹni-Mimọ́ Israeli. Ete mi yio yọ̀ gidigidi, nigbati mo ba nkọrin si ọ: ati ọkàn mi, ti iwọ ti rapada. Ahọn mi pẹlu yio si ma sọ̀rọ ododo rẹ titi li ọjọ gbogbo: nitoriti nwọn dãmu, a si doju ti awọn tí nwá ifarapa mi.
Kà O. Daf 71
Feti si O. Daf 71
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 71:14-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò