O. Daf 71:1-5

O. Daf 71:1-5 YBCV

OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: lai máṣe jẹ ki a dãmu mi. Gbà mi nipa ododo rẹ, ki o si mu mi yọ̀: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbà mi. Iwọ ni ki o ṣe ibujoko apata mi, nibiti emi o gbe ma rè nigbagbogbo: iwọ ti paṣẹ lati gbà mi; nitori iwọ li apata ati odi agbara mi. Gbà mi, Ọlọrun mi, li ọwọ awọn enia buburu, li ọwọ alaiṣododo ati ìka ọkunrin. Nitori iwọ ni ireti mi, Oluwa Ọlọrun; iwọ ni igbẹkẹle mi lati igba ewe mi.