O. Daf 7:12-17

O. Daf 7:12-17 YBCV

Bi on kò ba yipada, yio si pọ́n idà rẹ̀ mu: o ti fà ọrun rẹ̀ le na, o ti mura rẹ̀ silẹ. O si ti pèse elo ikú silẹ fun u; o ti ṣe awọn ọfa rẹ̀ ni oniná. Kiyesi i, o nrọbi ẹ̀ṣẹ, o si loyun ìwa-ìka, o si bí eké jade. O ti wà ọ̀fin, o gbẹ́ ẹ, o si bọ́ sinu iho ti on na wà. Ìwa-ika rẹ̀ yio si pada si ori ara rẹ̀, ati ìwa-agbara rẹ̀ yio si sọ̀kalẹ bọ̀ si atari ara rẹ̀. Emi o yìn Oluwa gẹgẹ bi ododo rẹ̀: emi o si kọrin iyìn si orukọ Oluwa Ọga-ogo julọ.