ỌLỌRUN, gbà mi; nitoriti omi wọnni wọ̀ inu lọ si ọkàn mi. Emi rì ninu irà jijin, nibiti ibuduro kò si, emi de inu omi jijin wọnni, nibiti iṣan-omi ṣàn bò mi lori. Agara ẹkun mi da mi: ọfun mi gbẹ: oju kún mi nigbati emi duro de Ọlọrun mi. Awọn ti o korira mi lainidi jù irun ori mi lọ: awọn ti nṣe ọta mi laiṣẹ, ti iba pa mi run, nwọn lagbara: nigbana ni mo san ohun ti emi kò mu. Ọlọrun, iwọ mọ̀ wère mi, ẹ̀ṣẹ mi kò si lumọ kuro loju rẹ. Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, máṣe jẹ ki oju ki o tì awọn ti o duro de ọ nitori mi: máṣe jẹ ki awọn ti nwá ọ ki o damu nitori mi, Ọlọrun Israeli.
Kà O. Daf 69
Feti si O. Daf 69
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 69:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò