O. Daf 68:32-35

O. Daf 68:32-35 YBCV

Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹnyin ijọba aiye; ẹ kọrin iyìn si Oluwa. Si ẹniti ngùn ati ọrun de ọrun atijọ; wò o, o fọhùn rẹ̀, eyi na li ohùn nla. Ẹ jẹwọ agbara fun Ọlọrun; ọlá-nla rẹ̀ wà lori Israeli, ati agbara rẹ̀ mbẹ li awọsanma. Ọlọrun, iwọ li ẹ̀ru lati ibi mimọ́ rẹ wọnni wá: Ọlọrun Israeli li On, ti nfi ilera ati agbara fun awọn enia rẹ̀. Olubukún li Ọlọrun!