O. Daf 66:16-20

O. Daf 66:16-20 YBCV

Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, emi o sọ ohun ti o ṣe fun ọkàn mi. Emi fi ẹnu mi kigbe pè e, emi o si fi àhọn mi buyin fun u. Bi emi ba gbà ẹ̀ṣẹ li aiya mi, Oluwa kì yio gbohùn mi: Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun ti gbohùn mi: o si ti fi eti si ohùn adura mi. Olubukún li Ọlọrun, ti kò yi adura mi pada kuro, tabi ãnu rẹ̀ kuro lọdọ mi.