O. Daf 65:1-4

O. Daf 65:1-4 YBCV

ỌLỌRUN, iyìn duro jẹ de ọ ni Sioni: ati si ọ li a o mu ileri ifẹ nì ṣẹ. Iwọ ti ngbọ́ adura, si ọdọ rẹ ni gbogbo enia mbọ̀. Ọ̀ran aiṣedede bori mi: bi o ṣe ti irekọja wa ni, iwọ ni yio wẹ̀ wọn nù kuro. Alabukún-fun li ẹniti iwọ yàn, ti iwọ si mu lati ma sunmọ ọdọ rẹ, ki o le ma gbe inu agbala rẹ wọnni: ore inu ile rẹ yio tẹ́ wa lọrùn, ani ti tempili mimọ́ rẹ.