O. Daf 62:5-12

O. Daf 62:5-12 YBCV

Ọkàn mi, iwọ sa duro jẹ de Ọlọrun; nitori lati ọdọ rẹ̀ wá ni ireti mi. On nikan li apata mi ati igbala mi: on li àbo mi; a kì yio ṣi mi ni ipò. Nipa Ọlọrun ni igbala mi, ati ogo mi: apata agbara mi, àbo mi si mbẹ ninu Ọlọrun. Gbẹkẹle e nigbagbogbo; ẹnyin enia, tú ọkàn nyin jade niwaju rẹ̀; Ọlọrun àbo fun wa. Nitõtọ asan li awọn ọmọ enia, eke si li awọn oloyè. Nwọn gòke ninu ìwọn, bakanna ni nwọn fẹrẹ jù asan lọ. Máṣe gbẹkẹle inilara, ki o má si ṣe gberaga li olè jija: bi ọrọ̀ ba npọ̀ si i, máṣe gbe ọkàn nyin le e. Ọlọrun ti sọ̀rọ lẹ̃kan; lẹ̃rinkeji ni mo gbọ́ eyi pe: ti Ọlọrun li agbara. Pẹlupẹlu, Oluwa, tirẹ li ãnu: nitoriti iwọ san a fun olukulùku enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.