O. Daf 6:4-9

O. Daf 6:4-9 YBCV

Pada, Oluwa, gbà ọkàn mi: gbà mi là nitori ãnu rẹ. Nitoriti kò si iranti rẹ ninu okú: ninu isa okú tani yio dupẹ fun ọ? Agara ikerora mi da mi: li oru gbogbo li emi nmu ẹní mi fó li oju omi; emi fi omije mi rin ibusùn mi. Oju mi bajẹ tan nitori ibinujẹ; o di ogbó tan nitori gbogbo awọn ọta mi. Ẹ lọ kuro lọdọ mi, gbogbo ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ; nitori ti Oluwa gbọ́ ohùn ẹkún mi. Oluwa gbọ́ ẹ̀bẹ mi; Oluwa yio gbà adura mi.