O. Daf 55:16-19

O. Daf 55:16-19 YBCV

Bi o ṣe ti emi ni, emi o kepè Ọlọrun; Oluwa yio si gbà mi. Li alẹ, li owurọ, ati li ọsan, li emi o ma gbadura, ti emi o si ma kigbe kikan: on o si gbohùn mi. O ti gbà ọkàn mi silẹ li alafia lọwọ ogun ti o ti dó tì mi: nitoripe pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ni nwọn dide si mi. Ọlọrun yio gbọ́, yio si pọ́n wọn loju, ani ẹniti o ti joko lati igbani. Nitoriti nwọn kò ni ayipada, nwọn kò si bẹ̀ru Ọlọrun.