O. Daf 55:1-7

O. Daf 55:1-7 YBCV

FETI si adura mi, Ọlọrun; má si ṣe fi ara rẹ pamọ kuro ninu ẹ̀bẹ mi. Fiye si mi, ki o si da mi lohùn: ara mi kò lelẹ ninu aroye mi, emi si npariwo; Nitori ohùn ọta nì, nitori inilara enia buburu: nitoriti nwọn mu ibi ba mi, ati ni ibinu, nwọn dẹkun fun mi. Aiya dùn mi gidigidi ninu mi: ipaiya ikú si ṣubu lù mi. Ibẹ̀ru ati ìwárìrì wá si ara mi, ati ibẹ̀ru ikú bò mi mọlẹ. Emi si wipe, A! iba ṣe pe emi ni iyẹ-apa bi àdaba! emi iba fò lọ, emi a si simi. Kiyesi i, emi iba rìn lọ si ọ̀na jijin rére, emi a si ma gbe li aginju.