O. Daf 51:7-15

O. Daf 51:7-15 YBCV

Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi o si mọ́: wẹ̀ mi, emi o si fún jù ẹ̀gbọn-owu lọ. Mu mi gbọ́ ayọ̀ ati inu didùn; ki awọn egungun ti iwọ ti rún ki o le ma yọ̀. Pa oju rẹ mọ́ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi, ki iwọ ki o si nù gbogbo aiṣedede mi nù kuro. Da aiya titun sinu mi, Ọlọrun; ki o si tún ọkàn diduroṣinṣin ṣe sinu mi. Máṣe ṣa mi tì kuro niwaju rẹ; ki o má si ṣe gbà Ẹmi mimọ́ rẹ lọwọ mi. Mu ayọ̀ igbala rẹ pada tọ̀ mi wá; ki o si fi ẹmi omnira rẹ gbé mi duro. Nigbana li emi o ma kọ́ awọn olurekọja li ọ̀na rẹ: awọn ẹlẹṣẹ yio si ma yipada si ọ. Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹbi ẹ̀jẹ, iwọ Ọlọrun igbala mi: ahọn mi yio si ma kọrin ododo rẹ kikan. Oluwa, iwọ ṣi mi li ète; ẹnu mi yio si ma fi iyìn rẹ han