O. Daf 48:1-3

O. Daf 48:1-3 YBCV

ẸNI-NLA ni Oluwa, ti ã yìn pupọpupọ, ni ilu Ọlọrun wa, li oke ìwa-mimọ́ rẹ̀. Didara ni ipò itẹdo, ayọ̀ gbogbo aiye li òke Sioni, ni iha ariwa, ilu Ọba nla. A mọ̀ Ọlọrun li àbo ninu ãfin rẹ̀.