Rán imọlẹ rẹ ati otitọ rẹ jade, ki nwọn ki o ma ṣe amọna mi: ki nwọn ki o mu mi gùn òke mimọ́ rẹ, ati sinu agọ rẹ wọnni. Nigbana li emi o lọ si ibi pẹpẹ Ọlọrun, sọdọ Ọlọrun ayọ̀ nla mi: nitõtọ, lara duru li emi o ma yìn ọ, Ọlọrun, Ọlọrun mi. Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitoriti emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi, ati Ọlọrun mi.
Kà O. Daf 43
Feti si O. Daf 43
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 43:3-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò